17/12/2025
IWULO EWE INA FUNFUN
(HEALTH BENEFITS OF JATROPHA CURCAS)
Ewe INA orisi Meji ni o Wa, EWE INA PUPA Ati EWE INA FUNFUN, Sugbon EWE INA FUNFUN Ohun ni a Fe Soro lelori.
Ewe yi wopo ni Awujo wa dada, papa ni Ile Yoruba, igi re a ma ga bi iwon Ese Bata mefa (6ft) Tabi ju beelo, bi Aye basegba igi yi si ni o se ma nga to.
Iwadi imo Ijinle jeki o yewa pe, Ewe yi ni Oniruru Eronja TI o ma nmu Adinku ba irora
(Reduces Pain), bakana, o ma nmu Adinku ba Oju Egbo TI o ba wu, pon, Tita, Tabi TI o bani Oyun Ninu (Inflammation).
Orisirisi ona ni a le gba lo Ewe yi fun Titoju IWOSAN Ara, bakana Otun ni awon ona Miran ti a tunle gba lati lo Ewe yi fun Idabobo Ati fun ki Igbesi Aye Eni ki o leni ojutu (Spiritual Uses).
FUN EYIKEYI KOKORO ARA
Ki a ja Ewe yi ni Tutu, ki a gun laiko fi omi kankan si, Omi ti o bajade larare ni ki a po papo mo Eyikeyi Ose ti o ba wuwa.
LILO RE
Ki a Mafi Ose na ra Gbogbo ibi ti KOKORO na Bawa pelu Omi, leyin bi wakati Meji, ki a wa lowe.
Pelu Ogo olohun oba, Gbogbo Eyikeyi Iran kokoro ti o baje, kokoro na yi o lo ni.
AWOKA/EGUN RIRO
(RHEUMATISM/ARTHRITIS)
Ki a ja Ewe yi Tutu Ati Egbo re, ki a se lagbo ki I jina dada leyin TI a TI fonu ki o Mo dada tan fun bi Ogbon iseju (30min), ki a ro sinu ike TI o bamo dada.
LILO RE
Mimu ni Idaji Stainless cup kan Emeji lojumo.
Pelu ogo olohun oba,Ipenija AWOKA Tabi EGUN RIRO na yi o lo patapata ni.
JEDIJEDI/IGBE GBUURU
(DYSENTERY/DIARRHEA)
Epo igi yi lasan ni ki a gbiyanju lati pa,ki a wa gun ki o kuna dada pelu EWE re na, ki a sa ki o gbe, ki Eni na ki o Mafi mu Ogi Gbigbona ni odiwon Sibi Imuko kan ni Emeta lojumo.
AKOKORO EYIN (TOOTHACHE PROBLEM)
ki Eni ti AKOKORO ba no lenu ki o ja Tutu Omudun Ewe yi ni owuro kutukutu,ki o Wa fi owo gbo dada, ki o Wa kan Omi ewe yi si okankan ibi eyin na.
Pelu ogo olohun oba, lesekese ni Irora na yi o dinku,ti AKOKORO na yi o si san larin ojo Meji si meta.
Kiise Gbogbo IWULO EWE INA FUNFUN yi ni a se alaye re tan sugbon ao tun matesiwaju nigbamiran.
Iwo na Bawa share re fun Anfani Awon Elomiran.
Ire o!